Kronika Kinni 8 BM

Àwọn Ìran Bẹnjamini

1 Bẹnjamini bí ọmọkunrin marun-un, Bela ni àkọ́bí, lẹ́yìn rẹ̀ ni Aṣibeli,

2 lẹ́yìn rẹ̀, Ahara, lẹ́yìn rẹ̀, Nohahi, àbíkẹ́yìn rẹ̀ ni, Rafa.

3 Àwọn ọmọ Bela ni: Adari, Gera, ati Abihudi,

4 Abiṣua, Naamani, ati Ahoa,

5 Gera, Ṣefufani, ati Huramu.

6 Àwọn wọnyi ni ìran Ehudu: (Àwọn baálé baálé ninu ìran Geba, tí wọ́n kó lẹ́rú lọ sí ìlú Manahati):

7 Naamani, Ahija ati Gera, tí ń jẹ́ Hegilamu, baba Usa, ati Ahihudu.

8 Lẹ́yìn tí Ṣaharaimu ti kọ àwọn iyawo rẹ̀ mejeeji, Huṣimu ati Baara sílẹ̀, ó fẹ́ Hodeṣi, ó sì bímọ ní ilẹ̀ Moabu.

9 Ọmọ meje ni Hodeṣi bí fún un: Jobabu, Sibia, Meṣa, ati Malikami,

10 Jeusi, Sakia ati Mirima. Gbogbo wọn jẹ́ baálé baálé ní ìdílé wọn.

11 Huṣimu náà bí ọmọkunrin meji fún un: Abitubu ati Elipaali.

12 Elipaali bí ọmọkunrin mẹta: Eberi, Miṣamu ati Ṣemedi. Ṣemedi yìí ni ó kọ́ àwọn ìlú Ono, Lodi, ati gbogbo àwọn ìletò tí ó yí wọn ká.

Àwọn Ará Bẹnjamini Tí Wọ́n Wà Ní Gati ati Aijaloni

13 Beraya ati Ṣema ni olórí àwọn ìdílé tí wọn ń gbé ìlú Aijaloni, àwọn sì ni wọ́n lé àwọn tí wọn ń gbé ìlú Gati tẹ́lẹ̀ kúrò;

14 àwọn ọmọ Beraya ni: Ahio, Ṣaṣaki, ati Jeremotu,

15 Sebadaya, Aradi, ati Ederi,

16 Mikaeli, Iṣipa ati Joha.

Àwọn Ará Bẹnjamini ní Jerusalẹmu

17 Àwọn ọmọ Elipaali ni: Sebadaya, Meṣulamu, Hiṣiki, ati Heberi,

18 Iṣimerai, Isilaya ati Jobabu.

19 Àwọn ọmọ Ṣimei ni: Jakimu, Sikiri, ati Sabidi;

20 Elienai, Siletai, ati Elieli;

21 Adaaya, Beraaya ati Ṣimirati;

22 Àwọn ọmọ Ṣaṣaki nìwọ̀nyí: Iṣipani, Eberi, ati Elieli;

23 Abidoni, Sikiri, ati Hanani;

24 Hananaya, Elamu, ati Antotija;

25 Ifideaya ati Penueli.

26 Àwọn ọmọ Jerohamu ni: Ṣamṣerai, Ṣeharaya, ati Atalaya;

27 Jaareṣaya, Elija ati Sikiri.

28 Àwọn ni baálé baálé ní ìdílé wọn, ìjòyè ni wọ́n ní ìran wọn; wọ́n ń gbé Jerusalẹmu.

Àwọn Ará Bẹnjamini tí Wọ́n Wà ní Gibeoni ati Jerusalẹmu

29 Jeieli, baba Gibeoni, ń gbé ìlú Gibeoni, Maaka ni orúkọ iyawo rẹ̀.

30 Abidoni ni àkọ́bí rẹ̀, lẹ́yìn rẹ̀ ni ó bí: Suri, Kiṣi, Baali, ati Nadabu;

31 Gedori, Ahio, Sekeri, ati

32 Mikilotu (baba Ṣimea). Wọ́n ń bá àwọn arakunrin wọn gbé, àdúgbò wọn kọjú sí ara wọn ní Jerusalẹmu.

Ìdílé Saulu Ọba

33 Neri ni baba Kiṣi, Kiṣi ni ó bí Saulu, Saulu sì bí àwọn ọmọkunrin mẹrin: Jonatani, Malikiṣua, Abinadabu, ati Eṣibaali.

34 Jonatani bí Meribibaali, Meribibaali sì bí Mika.

35 Mika bí ọmọkunrin mẹrin: Pitoni, Meleki, Tarea ati Ahasi.

36 Ahasi ni baba Jehoada. Jehoada sì ni baba: Alemeti, Asimafeti, ati Simiri. Simiri ni ó bí Mosa.

37 Mosa bí Binea; Binea bí Rafa, Rafa bí Eleasa, Eleasa sì bí Aseli.

38 Aseli bí ọmọkunrin mẹfa: Asirikamu, Bokeru, Iṣimaeli, Ṣearaya, Ọbadaya, ati Hanani. Aseli ni baba gbogbo wọn.

39 Eṣeki, arakunrin Aseli, bí ọmọ mẹta: Ulamu ni àkọ́bí rẹ̀, lẹ́yìn náà Jeuṣi, lẹ́yìn náà Elifeleti.

40 Àwọn ọmọ Ulamu jẹ́ jagunjagun, tafàtafà ni wọ́n, wọ́n sì lókìkí. Àwọn ọmọ ati ọmọ ọmọ rẹ̀ pọ̀. Aadọjọ ni wọ́n, ara ẹ̀yà Bẹnjamini sì ni gbogbo wọ́n.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29