1 Nítorí náà Dafidi pàṣẹ pé, “Ibí yìí ni ilé OLUWA Ọlọrun, ati pẹpẹ ẹbọ sísun yóo wà fún Israẹli.”
2 Dafidi pàṣẹ pé kí gbogbo àwọn àjèjì tí wọn ń gbé ilẹ̀ Israẹli péjọ, ó bẹ̀rẹ̀ sí kó wọn ṣiṣẹ́, ara wọn ni wọ́n gbẹ́ òkúta fún kíkọ́ tẹmpili.
3 Ó kó ọpọlọpọ irin jọ, tí wọn óo fi rọ ìṣó, tí wọn yóo fi kan àwọn ìlẹ̀kùn ati ìdè, ó kó idẹ jọ lọpọlọpọ pẹlu, ju ohun tí ẹnikẹ́ni lè wọ̀n lọ,
4 ati ọpọlọpọ igi kedari. Ó pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí eniyan kò le kà wọ́n, nítorí pé ọpọlọpọ igi kedari ni àwọn ará Sidoni ati Tire kó wá fún Dafidi.
5 Nítorí pe Dafidi ní, “Tẹmpili tí a óo kọ́ fún OLUWA gbọdọ̀ dára tóbẹ́ẹ̀ tí òkìkí rẹ̀ yóo kàn ká gbogbo ayé; bẹ́ẹ̀ sì ni Solomoni, ọmọ mi, tí yóo kọ́ ilé náà kéré, kò sì tíì ní ìrírí pupọ. Nítorí náà, n óo tọ́jú àwọn ohun èlò sílẹ̀ fún un.” Dafidi bá tọ́jú àwọn nǹkan tí wọn yóo lò sílẹ̀ lọpọlọpọ kí ó tó kú.
6 Dafidi bá pe Solomoni, ọmọ rẹ̀, ó pàṣẹ fún un pé kí ó kọ́ ilé kan fún OLUWA Ọlọrun Israẹli.
7 Ó ní, “Ọmọ mi, mo ní i lọ́kàn láti kọ́ tẹmpili kan fún orúkọ OLUWA Ọlọrun mi,
8 ṣugbọn OLUWA sọ fún mi pé mo ti ta ọpọlọpọ ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀, mo sì ti ja ọpọlọpọ ogun; nítorí ọpọlọpọ ìtàjẹ̀sílẹ̀ náà, òun kò ní gbà pé kí n kọ́ tẹmpili òun.
9 OLUWA ní n óo bí ọmọkunrin kan tí ìjọba rẹ̀ yóo jẹ́ ìjọba alaafia, ó ní òun óo fún un ní alaafia, gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ yíká kò sì ní yọ ọ́ lẹ́nu. Solomoni ni orúkọ rẹ̀ yóo máa jẹ́. Ní ìgbà tirẹ̀, Israẹli yóo wà ní alaafia ati àìléwu.
10 Ó ní ọmọ náà ni yóo kọ́ ilé fún òun. Yóo jẹ́ ọmọ òun, òun náà yóo sì jẹ́ baba rẹ̀. Ó ní òun óo fìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ ní Israẹli títí lae.
11 “Nisinsinyii, ìwọ ọmọ mi, OLUWA yóo wà pẹlu rẹ, kí o lè kọ́ ilé OLUWA Ọlọrun rẹ fún un gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ nípa rẹ.
12 Kí OLUWA fún ọ ní ọgbọ́n ati làákàyè kí o lè máa pa òfin OLUWA Ọlọrun rẹ mọ́ nígbà tí ó bá fi ọ́ jọba lórí Israẹli.
13 Bí o bá pa gbogbo òfin tí Ọlọrun fún Israẹli láti ọwọ́ Mose mọ́, o óo ṣe rere. Múra, kí o sì ṣe ọkàn gírí, má bẹ̀rù, má sì ṣe jẹ́ kí àyà fò ọ́.
14 Mo ti sa gbogbo agbára mi láti tọ́jú ọ̀kẹ́ marun-un (100,000) talẹnti wúrà kalẹ̀ fún kíkọ́ ilé OLUWA, aadọta ọ̀kẹ́ (1,000,000) talẹnti fadaka, ati idẹ, ati irin tí ó pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò lè wọ̀n. Mo ti tọ́jú òkúta ati pákó pẹlu. O gbọdọ̀ wá kún un.
15 O ní ọpọlọpọ òṣìṣẹ́: àwọn agbẹ́kùúta, àwọn ọ̀mọ̀lé, àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà, ati oríṣìíríṣìí àwọn oníṣẹ́ ọnà tí kò lóǹkà,
16 àwọn alágbẹ̀dẹ wúrà, ati ti fadaka, ti idẹ, ati ti irin. Bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ náà nisinsinyii! Kí OLUWA wà pẹlu rẹ!”
17 Dafidi pàṣẹ fún gbogbo àwọn àgbààgbà Israẹli pé kí wọ́n ran Solomoni, ọmọ òun lọ́wọ́.
18 Ó ní, “Ǹjẹ́ OLUWA Ọlọrun yín kò ha wà pẹlu yín? Ǹjẹ́ kò ti fun yín ní ìfọ̀kànbalẹ̀ káàkiri? Nítorí pé ó ti jẹ́ kí n ṣẹgun gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yìí, ilẹ̀ náà sì wà lábẹ́ àkóso OLUWA ati ti àwọn eniyan rẹ̀.
19 Nítorí náà, ẹ fi tọkàntọkàn wá OLUWA Ọlọrun yín nisinsinyii. Ẹ múra kí ẹ kọ́ ilé ìsìn fún OLUWA Ọlọrun, kí ẹ baà lè gbé Àpótí Majẹmu OLUWA ati gbogbo ohun èlò mímọ́ fún ìsìn Ọlọrun lọ sinu ilé tí ẹ óo kọ́ fún OLUWA.”