1 Dafidi ọba pe gbogbo àwọn olórí ní ilẹ̀ Israẹli jọ sí Jerusalẹmu, àwọn olórí láàrin àwọn ẹ̀yà Israẹli, àwọn olórí àwọn ìpín tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ fún ọba, àwọn ọ̀gágun ẹgbẹẹgbẹrun ọmọ ogun, ati ọgọọgọrun-un ọmọ ogun, gbogbo àwọn tí wọ́n jẹ́ alabojuto ohun ìní ati ẹran ọ̀sìn ọba, àwọn tí wọ́n ń tọ́jú àwọn ọmọ ọba, àwọn tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ ní ààfin, àwọn eniyan pataki pataki ati àwọn akọni ọmọ ogun, gbogbo wọn péjọ sí Jerusalẹmu.
2 Dafidi bá dìde dúró, ó ní, “Ẹ gbọ́ mi, ẹ̀yin ará mi ati eniyan mi, mo ní i lọ́kàn láti kọ́ ilé ìsinmi fún Àpótí Majẹmu OLUWA, ati fún àpótí ìtìsẹ̀ Ọlọrun wa; mo ti tọ́jú gbogbo nǹkan sílẹ̀, mo sì ti múra tán.
3 Ṣugbọn, Ọlọrun sọ fún mi pé, kì í ṣe èmi ni n óo kọ́ ilé fún òun, nítorí pé jagunjagun ni mí, mo sì ti ta ẹ̀jẹ̀ pupọ sílẹ̀.
4 Sibẹsibẹ OLUWA Ọlọrun Israẹli yàn mí ninu ilé baba mi láti jọba lórí Israẹli títí lae; nítorí pé ó yan ẹ̀yà Juda láti ṣe aṣaaju Israẹli. Ninu ẹ̀yà Juda, ó yan ilé baba mi, láàrin àwọn ọmọ baba mi, ó ní inú dídùn sí mi, ó fi mí jọba lórí gbogbo Israẹli.
5 OLUWA fún mi ní ọmọ pupọ, ṣugbọn ninu gbogbo wọn, ó yan Solomoni láti jọba lórí ìtẹ́ ìjọba rẹ̀ lórí Israẹli.
6 “OLUWA sọ fún mi pé, ‘Solomoni, ọmọ rẹ ni yóo kọ́ ilé mi ati àgbàlá mi, nítorí mo ti yàn án láti jẹ́ ọmọ mi, èmi yóo sì jẹ́ baba fún un.
7 N óo fi ìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ títí lae, bí ó bá ti pinnu láti máa pa òfin ati ìlànà mi mọ́, gẹ́gẹ́ bí ó ti ń ṣe nisinsinyii.’
8 “Nítorí náà, lójú gbogbo ọmọ Israẹli, lójú ìjọ eniyan OLUWA, ati ní etígbọ̀ọ́ Ọlọrun wa, mò ń kìlọ̀ fun yín pé kí ẹ máa pa gbogbo òfin OLUWA Ọlọrun yín mọ́, kí ẹ̀yin ati arọmọdọmọ yín baà lè máa gbé ilẹ̀ yìí títí lae.
9 “Ìwọ Solomoni, ọmọ mi, mọ Ọlọrun àwọn baba rẹ, kí o sì fi gbogbo ọkàn rẹ sìn ín tìfẹ́tìfẹ́, nítorí OLUWA a máa wádìí ọkàn, ó sì mọ gbogbo èrò ati ète eniyan. Bí o bá wá OLUWA, o óo rí i, ṣugbọn bí o bá kọ̀ ọ́ sílẹ̀, yóo ta ọ́ nù títí lae.
10 Kíyèsára, nítorí pé OLUWA ti yàn ọ́ láti kọ́ ilé kan tí yóo jẹ́ ibi mímọ́, ṣe gírí, kí o sì kọ́ ọ.”
11 Dafidi bá fún Solomoni ní àwòrán tẹmpili náà tí wọ́n fi ọwọ́ yà, ati ti àwọn ilé mìíràn tí yóo kọ́ mọ́ tẹmpili, ati ti àwọn ilé ìṣúra rẹ̀, àwọn yàrá òkè, àwọn yàrá ti inú, ati ti yàrá ìtẹ́ àánú;
12 ati àwòrán gbogbo ohun tí ó ní lọ́kàn láti ṣe sinu àgbàlá ilé OLUWA, ati ti àwọn yàrá káàkiri, àwọn ilé ìṣúra tí yóo wà ninu ilé Ọlọrun, ati ti àwọn ilé ìṣúra tí wọ́n o máa kó ohun tí a yà sọ́tọ̀ fún OLUWA pamọ́ sí.
13 Dafidi tún fún un ní ìwé ètò pípín àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi sí ìsọ̀rí-ìsọ̀rí, ati ètò gbogbo iṣẹ́ ìsìn inú ilé OLUWA, ti àwọn ohun èlò fún ìsìn ninu ilé OLUWA;
14 àkọsílẹ̀ ìwọ̀n wúrà fún gbogbo ohun èlò wúrà fún ìsìn kọ̀ọ̀kan, ti ìwọ̀n fadaka fún gbogbo ohun èlò fadaka fún ìsìn kọ̀ọ̀kan,
15 ti ìwọ̀n àwọn ọ̀pá fìtílà wúrà ati àwọn fìtílà wọn, ti ìwọ̀n fadaka fún ọ̀pá fìtílà kan ati àwọn fìtílà wọn, gẹ́gẹ́ bí ìlò olukuluku wọn ninu ìsìn.
16 Ètò ìwọ̀n wúrà fún tabili àkàrà ìfihàn kọ̀ọ̀kan ati ìwọ̀n fadaka fún tabili fadaka kọ̀ọ̀kan,
17 ìwọ̀n ojúlówó wúrà fún àwọn àmúga tí a fi ń mú ẹran, àwọn agbada, àwọn ife, àwọn abọ́ wúrà ati ti ìwọ̀n abọ́ fadaka kọ̀ọ̀kan,
18 ìwọ̀n pẹpẹ turari tí a fi wúrà yíyọ́ ṣe ati ohun tí ó ní lọ́kàn nípa àwọn kẹ̀kẹ́ wúrà àwọn Kerubu tí wọ́n na ìyẹ́ wọn bo Àpótí Majẹmu OLUWA.
19 Gbogbo nǹkan wọnyi ni ó kọ sílẹ̀ fínnífínní gẹ́gẹ́ bí ìlànà láti ọ̀dọ̀ OLUWA nípa iṣẹ́ inú tẹmpili; ó ní gbogbo rẹ̀ ni wọ́n sì gbọdọ̀ ṣe gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ náà.
20 Dafidi bá sọ fún Solomoni, ọmọ rẹ̀ pé, “Múra gírí, mú ọkàn le, kí o sì ṣe bí mo ti wí. Má bẹ̀rù, má sì jẹ́ kí ọkàn rẹ rẹ̀wẹ̀sì; nítorí OLUWA Ọlọrun, àní Ọlọrun mi, wà pẹlu rẹ. Kò ní já ọ kulẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò ní kọ̀ ọ́ sílẹ̀, títí tí iṣẹ́ ilé OLUWA yóo fi parí.
21 Gbogbo ètò iṣẹ́ ati pípín àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi ninu tẹmpili ni a ti ṣe fínnífínní. Àwọn tí wọ́n mọ oríṣìíríṣìí iṣẹ́ yóo wà pẹlu rẹ, bákan náà, àwọn olórí ati gbogbo eniyan Israẹli yóo wà lábẹ́ àṣẹ rẹ.”