2 Dafidi ṣí adé wúrà orí ọba wọn, ó sì rí i pé adé náà wọ̀n tó ìwọ̀n talẹnti wúrà kan, òkúta olówó iyebíye kan sì wà lára rẹ̀; wọ́n bá fi dé Dafidi lórí. Dafidi sì tún kó ọpọlọpọ ìkógun mìíràn ninu ìlú náà.
Ka pipe ipin Kronika Kinni 20
Wo Kronika Kinni 20:2 ni o tọ