1 Àwọn wọnyi ni àwọn olórí ìdílé ati olórí ẹgbẹẹgbẹrun ọmọ ogun ati olórí ọgọọgọrun-un ọmọ ogun, ati àwọn olórí tí wọ́n jẹ́ aṣojú ọba ní gbogbo ìpínlẹ̀ ní oṣooṣù, títí ọdún yóo fi yípo ni wọn máa ń yan ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbaaji (24,000) eniyan, tí wọn ń pààrọ̀ ara wọn.
2 Jaṣobeamu, ọmọ Sabidieli, ni olórí ìpín kinni, fún oṣù kinni; iye àwọn tí wọ́n wà ninu ìpín rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbaaji.
3 Ìran Peresi ni Jaṣobeamu, òun sì ni balogun fún gbogbo àwọn ọ̀gágun fún oṣù kinni.
4 Dodai, láti inú ìran Ahohi, ni olórí ìpín ti oṣù keji, iye àwọn tí wọ́n wà ninu ìpín rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbaaji (24,000).