51 baba Buki, baba Usi, baba Serahaya;
52 baba Meraiotu, baba Amaraya, baba Ahitubu;
53 baba Sadoku, baba Ahimaasi.
54 Ilẹ̀ tí a pín fún ìran Aaroni nìyí, pẹlu ààlà wọn: ìdílé Kohati ni a kọ́kọ́ pín ilẹ̀ fún ninu àwọn ọmọ Lefi.
55 Wọ́n fún wọn ní ìlú Heburoni ní ilẹ̀ Juda, ati gbogbo ilẹ̀ pápá oko tí ó yí i ká,
56 ṣugbọn Kalebu ọmọ Jefune ni wọ́n fún ní ìgbèríko ati ìletò tí ó yí ìlú Heburoni ká.
57 Àwọn ọmọ Aaroni ni a pín àwọn ìlú ààbò wọnyi fún: Heburoni, Libina, Jatiri ati Eṣitemoa, pẹlu àwọn pápá oko tí ó yí wọn ká.