58 Bẹ́ẹ̀ náà ni Hileni, ati Debiri,
59 ati Aṣani ati Beti Ṣemeṣi pẹlu pápá oko tí ó yí wọn ká.
60 Àwọn ìlú tí wọ́n pín fún wọn, ninu ilẹ̀ ẹ̀yà Bẹnjamini nìwọ̀nyí: Geba, Alemeti, ati Anatoti, pẹlu pápá oko tí ó yí wọn ká. Gbogbo àwọn ìlú tí ó jẹ́ tiwọn ní gbogbo ìdílé wọn jẹ́ mẹtala.
61 Gègé ni wọ́n ṣẹ́ lórí ìlú mẹ́wàá ara ilẹ̀ ìdajì ẹ̀yà Manase tí ó wà ní ìhà ìwọ̀ oòrùn, tí wọn sì pín wọn fún àwọn ìdílé Kohati tí ó kù.
62 Ìlú mẹtala ni wọ́n pín fún àwọn ọmọ Geriṣomu ní ìdílé ìdílé lára àwọn ìlú ẹ̀yà Isakari, Aṣeri, Nafutali, ati ìdajì ẹ̀yà Manase, tí wọ́n wà ní ilẹ̀ Baṣani.
63 Ìlú mejila ni wọ́n pín fún àwọn ọmọ Merari ní ìdílé ìdílé, lára àwọn ìlú ẹ̀yà Reubẹni, Gadi ati ti Sebuluni.
64 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Israẹli ṣe fún àwọn ọmọ Lefi ní gbogbo àwọn ìlú ńláńlá pẹlu àwọn pápá oko tí ó yí wọn ká.