16 A kò gbọdọ pa awọn baba nitori ẹ̀ṣẹ awọn ọmọ, bẹ̃ni a kò gbọdọ pa awọn ọmọ nitori awọn baba: olukuluku enia li a o pa nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀.
17 Iwọ kò gbọdọ yi idajọ alejò po, tabi ti alainibaba; bẹ̃ni ki iwọ ki o máṣe gbà aṣọ opó ni ogò:
18 Ṣugbọn ki iwọ ki o ranti pe iwọ ti ṣe ẹrú ni Egipti, OLUWA Ọlọrun rẹ si gbà ọ silẹ kuro nibẹ̀: nitorina ni mo ṣe paṣẹ fun ọ lati ma ṣe nkan yi.
19 Nigbati iwọ ba kore rẹ li oko rẹ, ti iwọ ba si gbagbé ití-ọkà kan silẹ ninu oko, ki iwọ ki o máṣe pada lọ mú u: ki o le ma jẹ́ ti alejò, ti alainibaba, ati ti opó: ki OLUWA Ọlọrun rẹ ki o le ma busi i fun ọ, ninu iṣẹ ọwọ́ rẹ gbogbo.
20 Nigbati iwọ ba ngún igi olifi rẹ, ki iwọ ki o máṣe tun pada wò ẹka rẹ̀: ki eyinì ki o jẹ́ ti alejò, ti alainibaba, ati ti opó.
21 Nigbati iwọ ba nká eso ọgbà-àjara rẹ, ki iwọ ki o máṣe peṣẹ́ lẹhin rẹ: ki eyinì ki o jẹ́ ti alejò, ti alainibaba, ati ti opó.
22 Ki iwọ ki o si ma ranti pe iwọ ti ṣe ẹrú ni ilẹ Egipti: nitorina ni mo ṣe paṣẹ fun ọ lati ma ṣe nkan yi.