1 BI gbolohùn-asọ̀ kan ba wà lãrin enia, ti nwọn si wá si ibi idajọ, ti nwọn si dajọ wọn; nigbana ni ki nwọn ki o fi are fun alare, ki nwọn ki o si fi ẹbi fun ẹlẹbi;
2 Yio si ṣe, bi ẹlẹbi na ba yẹ lati nà, ki onidajọ na ki o da a dọbalẹ, ki o si mu ki a nà a ni iye kan li oju on, gẹgẹ bi ìwabuburu rẹ̀.
3 Ogoji paṣan ni ki a nà a, kò gbọdọ lé: nitoripe bi o ba lé, ti o ba si fi paṣan pupọ̀ nà a jù wọnyi lọ, njẹ arakunrin rẹ yio di gigàn li oju rẹ.
4 Máṣe di akọ-malu li ẹnu nigbati o ba npakà.
5 Bi awọn arakunrin ba ngbé pọ̀, ti ọkan ninu wọn ba si kú, ti kò si lí ọmọkunrin, ki aya okú ki o máṣe ní alejò ara ode li ọkọ: arakunrin ọkọ rẹ ni ki o wọle tọ̀ ọ, ki o si ní i li aya, ki o si ṣe iṣẹ arakunrin ọkọ fun u.
6 Yio si ṣe, akọ́bi ọmọ ti o bi ki o rọpò li orukọ arakunrin rẹ̀ ti o kú, ki orukọ rẹ̀ ki o má ba parẹ́ ni Israeli.
7 Bi ọkunrin na kò ba si fẹ́ lati mú aya arakunrin rẹ̀, njẹ ki aya arakunrin rẹ̀ ki o gòke lọ si ẹnubode tọ̀ awọn àgba lọ, ki o si wipe, Arakunrin ọkọ mi kọ̀ lati gbé orukọ arakunrin rẹ̀ ró ni Israeli, on kò fẹ́ ṣe iṣẹ arakunrin ọkọ mi.