23 Ati pe gbogbo ilẹ rẹ̀ di imi-õrùn, ati iyọ̀, ati ijóna, ti a kò le gbìn nkan si, tabi ti kò le seso, tabi ti koriko kò le hù ninu rẹ̀, bi ibìṣubu Sodomu, ati Gomorra, Adma, ati Seboiimu, ti OLUWA bìṣubu ninu ibinu rẹ̀, ati ninu ikannu rẹ̀:
24 Ani gbogbo orilẹ-ède yio ma wipe, Ẽṣe ti OLUWA fi ṣe bayi si ilẹ yi? Kili a le mọ̀ õru ibinu nla yi si?
25 Nwọn o si wipe, Nitoriti nwọn kọ̀ majẹmu OLUWA, Ọlọrun awọn baba wọn silẹ, ti o ti bá wọn dá nigbati o mú wọn lati ilẹ Egipti jade wá.
26 Nitoriti nwọn lọ, nwọn si bọ oriṣa, nwọn si tẹriba fun wọn, oriṣa ti nwọn kò mọ̀ rí, ti on kò si fi fun wọn.
27 Ibinu OLUWA si rú si ilẹ na, lati mú gbogbo egún ti a kọ sinu iwé yi wá sori rẹ̀:
28 OLUWA si fà wọn tu kuro ni ilẹ wọn ni ibinu, ati ni ikannu, ati ni irunu nla, o si lé wọn lọ si ilẹ miran, bi o ti ri li oni yi.
29 Ti OLUWA Ọlọrun wa ni ohun ìkọkọ: ṣugbọn ohun ti afihàn ni tiwa ati ti awọn ọmọ wa lailai, ki awa ki o le ma ṣe gbogbo ọ̀rọ ofin yi.