7 Nigbati ẹnyin ti dé ihinyi, Sihoni ọba Hesboni, ati Ogu ọba Baṣani, jade ogun si wa, awa si kọlù wọn:
8 Awa si gbà ilẹ wọn, a si fi i fun awọn ọmọ Reubeni, ati awọn ọmọ Gadi, ati àbọ ẹ̀ya Manasse ni iní.
9 Nitorina, ẹ pa ọ̀rọ majẹmu yi mọ́, ki ẹ si ma ṣe wọn, ki ẹnyin ki o le ma ri ire ninu ohun gbogbo ti ẹnyin nṣe.
10 Gbogbo nyin li o duro li oni niwaju OLUWA Ọlọrun nyin; awọn olori nyin, awọn ẹ̀ya nyin, awọn àgba nyin, ati awọn ijoye nyin, ani gbogbo awọn ọkunrin Israeli,
11 Awọn ọmọ wẹ́wẹ nyin, awọn aya nyin, ati alejò rẹ, ti mbẹ lãrin ibudó rẹ, lati aṣẹgi rẹ dé apọnmi rẹ:
12 Ki iwọ ki o le wọ̀ inu majẹmu OLUWA Ọlọrun rẹ, ati ibura rẹ̀, ti OLUWA Ọlọrun rẹ bá ọ ṣe li oni:
13 Ki o le fi idi rẹ kalẹ li oni li enia kan fun ara rẹ̀, ati ki on ki o le ma ṣe Ọlọrun rẹ, bi o ti sọ fun ọ, ati bi o ti bura fun awọn baba rẹ, fun Abrahamu, fun Isaaki, ati fun Jakobu.