24 Ebi yio mu wọn gbẹ, oru gbigbona li a o fi run wọn, ati iparun kikorò; emi o si rán ehín ẹranko si wọn, pẹlu oró ohun ti nrakò ninu erupẹ.
25 Idà li ode, ati ipàiya ninu iyẹwu, ni yio run ati ọmọkunrin ati wundia, ọmọ ẹnu-ọmu, ati ọkunrin arugbo elewu irun pẹlu.
26 Mo wipe, Emi o tu wọn ká patapata, emi o si mu iranti wọn dá kuro ninu awọn enia:
27 Bikoṣepe bi mo ti bẹ̀ru ibinu ọtá, ki awọn ọtá wọn ki o má ba ṣe alaimọ̀, ati ki nwọn ki o má ba wipe, Ọwọ́ wa leke ni, ki isi ṣe OLUWA li o ṣe gbogbo eyi.
28 Nitori orilẹ-ède ti kò ní ìmọ ni nwọn, bẹ̃ni kò sí òye ninu wọn.
29 Ibaṣepe nwọn gbọ́n, ki òye eyi ki o yé wọn, nwọn iba rò igbẹhin wọn!
30 Ẹnikan iba ti ṣe lé ẹgbẹrun, ti ẹni meji iba si lé ẹgbãrun sá, bikoṣepe bi Apata wọn ti tà wọn, ti OLUWA si fi wọn tọrẹ?