14 OLUWA si paṣẹ fun mi ni ìgba na lati kọ́ nyin ni ìlana ati idajọ, ki ẹnyin ki o le ma ṣe wọn ni ilẹ na nibiti ẹnyin nlọ lati gbà a.
15 Nitorina ki ẹnyin ki o ma kiyesara nyin gidigidi, nitoripe ẹnyin kò ri apẹrẹ kan li ọjọ́ ti OLUWA bá nyin sọ̀rọ ni Horebu lati ãrin iná wá:
16 Ki ẹnyin ki o má ba bà ara nyin jẹ́, ki ẹ má si lọ ṣe ere gbigbẹ, apẹrẹ ohunkohun, aworán akọ tabi abo.
17 Aworán ẹrankẹran ti mbẹ lori ilẹ, aworán ẹiyẹkẹiyẹ ti nfò li oju-ọrun.
18 Aworán ohunkohun ti nrakò lori ilẹ, aworán ẹjakẹja ti mbẹ ninu omi nisalẹ ilẹ:
19 Ati ki iwọ ki o má ba gbé oju rẹ soke ọrun, nigbati iwọ ba si ri õrùn, ati oṣupa, ati irawọ, ani gbogbo ogun ọrun, ki a má ba sún ọ lọ ibọ wọn, ki o si ma sìn wọn, eyiti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun gbogbo orilẹ-ède labẹ ọrun gbogbo.
20 Ṣugbọn OLUWA ti gbà nyin, o si mú nyin lati ileru irin, lati Egipti jade wá, lati ma jẹ́ enia iní fun u, bi ẹnyin ti ri li oni yi.