9 Nitorina ki iwọ ki o mọ̀ pe, OLUWA Ọlọrun rẹ, on li Ọlọrun; Ọlọrun olõtọ, ti npa majẹmu mọ́ ati ãnu fun awọn ti o fẹ́ ẹ, ti nwọn si pa ofin rẹ̀ mọ́ dé ẹgbẹrun iran;
10 Ti o si nsan a pada fun awọn ti o korira rẹ̀ li oju wọn, lati run wọn: on ki yio jafara fun ẹniti o korira rẹ̀, on o san a fun u loju rẹ̀.
11 Nitorina ki iwọ ki o pa ofin, ati ìlana, ati idajọ mọ́, ti mo palaṣẹ fun ọ li oni, lati ma ṣe wọn.
12 Yio si ṣe, nitoriti ẹnyin fetisi idajọ wọnyi, ti ẹ si npa wọn mọ́, ti ẹ si nṣe wọn, njẹ OLUWA Ọlọrun rẹ yio ma pa majẹmu ati ãnu mọ́ fun ọ, ti o ti bura fun awọn baba rẹ:
13 On o si fẹ́ ọ, yio si bukún ọ, yio si mu ọ bisi i: on o si bukún ọmọ inu rẹ, ati eso ilẹ rẹ, ọkà rẹ, ati ọti-waini rẹ, ati oróro rẹ, ibisi malu rẹ, ati awọn ọmọ agbo-agutan rẹ, ni ilẹ na ti o ti bura fun awọn baba rẹ lati fi fun ọ.
14 Iwọ o jẹ́ ẹni ibukún jù gbogbo enia lọ: ki yio sí akọ tabi abo ninu nyin ti yio yàgan, tabi ninu ohunọ̀sin nyin.
15 OLUWA yio si gbà àrun gbogbo kuro lọdọ rẹ, ki yio si fi ọkan ninu àrun buburu Egipti, ti iwọ mọ̀, si ọ lara, ṣugbọn on o fi wọn lé ara gbogbo awọn ti o korira rẹ.