15 Ọba Egipti si wi fun awọn iyãgbà Heberu; orukọ ọkan ninu ẹniti ijẹ Ṣifra, ati orukọ ekeji ni Pua:
16 O si wipe, Nigbati ẹnyin ba nṣe iṣẹ iyãgbà fun awọn obinrin Heberu, ti ẹnyin ba ri wọn ni ikunlẹ; bi o ba ṣe ọmọkunrin ni, njẹ ki ẹnyin ki o pa a; ṣugbọn bi o ba ṣe ọmọbinrin ni, njẹ on o yè.
17 Ṣugbọn awọn iyãgbà bẹ̀ru Ọlọrun, nwọn kò si ṣe bi ọba Egipti ti fi aṣẹ fun wọn, nwọn si da awọn ọmọkunrin si.
18 Ọba Egipti si pè awọn iyãgbà na, o si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi ṣe irú nkan yi ti ẹnyin si da awọn ọmọkunrin si?
19 Awọn iyãgbà si wi fun Farao pe, nitoriti awọn obinrin Heberu kò ri bi awọn obinrin Egipti; nitoriti ara yá wọn, nwọn a si ti bí ki awọn iyãgbà to wọle tọ̀ wọn lọ.
20 Nitorina Ọlọrun ṣe rere fun awọn iyãgbà na: awọn enia na si mbisi i, nwọn si di alagbara koko.
21 O si ṣe, nitoriti awọn iyãgbà bẹ̀ru Ọlọrun, on si kọle fun wọn.