35 Awọn ọmọ Israeli si ṣe gẹgẹ bi ọ̀rọ Mose; nwọn si bère ohun-èlo fadaka, ati ohun-èlo wurà, ati aṣọ lọwọ awọn ara Egipti.
36 OLUWA si fun awọn enia na li ojurere li oju awọn ara Egipti, bẹ̃ni nwọn si fun wọn li ohun ti nwọn bère. Nwọn si kó ẹrù awọn ara Egipti.
37 Awọn ọmọ Israeli si rìn lati Ramesesi lọ si Sukkotu, nwọn to ìwọn ọgbọ̀n ọkẹ ẹlẹsẹ̀ ọkunrin, li àika ọmọde.
38 Ati ọ̀pọ enia ti o dàpọ mọ́ wọn bá wọn goke lọ pẹlu; ati agbo, ati ọwọ́-ẹran, ani ọ̀pọlọpọ ẹran.
39 Nwọn si yan àkara iyẹfun pipò alaiwu ti nwọn mú jade ti Egipti wá, nwọn kò sa fi iwukàra si i; nitoriti a tì wọn jade kuro ni Egipti, nwọn kò si le duro, bẹ̃ni nwọn kò pèse ohun jijẹ kan fun ara wọn.
40 Njẹ ìgba atipo awọn ọmọ Israeli ti nwọn ṣe ni ilẹ Egipti, o jẹ́ irinwo ọdún o le ọgbọ̀n.
41 O si ṣe li opin irinwo ọdún o le ọgbọ̀n, ani li ọjọ́ na gan, li o si ṣe ti gbogbo ogun OLUWA jade kuro ni ilẹ Egipti.