11 Yio si ṣe nigbati OLUWA ba mú ọ dé ilẹ awọn ara Kenaani, bi o ti bura fun ọ, ati fun awọn baba rẹ, ti yio si fi fun ọ.
12 Ni iwọ o si yà gbogbo akọ́bi sọ̀tọ fun OLUWA, ati gbogbo akọ́bi ẹran ti iwọ ni; ti OLUWA li awọn akọ.
13 Ati gbogbo akọ́bi kẹtẹkẹtẹ ni ki iwọ ki o fi ọdọ-agutan rapada; bi iwọ kò ba rà a pada, njẹ ki iwọ ki o sẹ ẹ li ọrùn: ati gbogbo akọ́bi enia ninu awọn ọmọ ọkunrin rẹ ni iwọ o rapada.
14 Yio si ṣe nigbati ọmọ rẹ yio bère lọwọ rẹ lẹhin-ọla pe, Kili eyi? ki iwọ ki o wi fun u pe, Ọwọ́ agbara li OLUWA fi mú wa jade kuro ni ilẹ Egipti, kuro li oko-ẹrú:
15 O si ṣe, nigbati Farao kọ̀ lati jẹ ki a lọ, on li OLUWA pa gbogbo akọ́bi ni ilẹ Egipti, ati akọ́bi enia, ati akọ́bi ẹran; nitorina ni mo ṣe fi gbogbo akọ́bi ti iṣe akọ rubọ si OLUWA; ṣugbọn gbogbo awọn akọ́bi ọmọ ọkunrin mi ni mo rapada.
16 Yio si ma ṣe àmi li ọwọ́ rẹ, ati ọjá-igbaju lagbedemeji oju rẹ: nitori ọwọ́ agbara li OLUWA fi mú wa jade kuro ni Egipti.
17 O si ṣe, nigbati Farao jẹ ki awọn enia na ki o lọ tán, Ọlọrun kò si mú wọn tọ̀ ọ̀na ilẹ awọn ara Filistia, eyi li o sa yá; nitoriti Ọlọrun wipe, Ki awọn enia má ba yi ọkàn pada nigbati nwọn ba ri ogun, ki nwọn si pada lọ si Egipti.