1 LI oṣù kẹta, ti awọn ọmọ Israeli jade kuro ni ilẹ Egipti tán, li ọjọ́ na gan ni nwọn dé ijù Sinai.
2 Nwọn sá ti ṣi kuro ni Refidimu, nwọn si wá si ijù Sinai, nwọn si dó si ijù na; nibẹ̀ ni Israeli si dó si niwaju oke na.
3 Mose si goke tọ̀ Ọlọrun lọ, OLUWA si kọ si i lati oke na wá wipe, Bayi ni ki iwọ ki o sọ fun ile Jakobu, ki o si wi fun awọn ọmọ Israeli pe;
4 Ẹnyin ti ri ohun ti mo ti ṣe si awọn ara Egipti, ati bi mo ti rù nyin li apa-ìyẹ́ idì, ti mo si mú nyin tọ̀ ara mi wá.
5 Njẹ nisisiyi, bi ẹnyin ba fẹ́ gbà ohùn mi gbọ́ nitõtọ, ti ẹ o si pa majẹmu mi mọ́, nigbana li ẹnyin o jẹ́ iṣura fun mi jù gbogbo enia lọ: nitori gbogbo aiye ni ti emi.