9 OLUWA si wi fun Mose pe, Wò o, emi tọ̀ ọ wá ninu awọsanma ṣíṣu, ki awọn enia ki o le ma gbọ́ nigbati mo ba mbá ọ sọ̀rọ, ki nwọn ki o si ma gbà ọ gbọ́ pẹlu lailai. Mose si sọ ọ̀rọ awọn enia na fun OLUWA.
10 OLUWA si wi fun Mose pe, Tọ̀ awọn enia yi lọ, ki o si yà wọn simimọ́ li oni ati li ọla, ki nwọn ki o si fọ̀ asọ wọn.
11 Ki nwọn ki o si mura dè ijọ́ kẹta: nitori ni ijọ́ kẹta OLUWA yio sọkalẹ sori oke Sinai li oju awọn enia gbogbo.
12 Ki iwọ ki o si sagbàra fun awọn enia yiká, pe, Ẹ ma kiyesi ara nyin, ki ẹ máṣe gùn ori oke lọ, ki ẹ má si ṣe fọwọbà eti rẹ̀: ẹnikẹni ti o ba fọwọkàn oke na, pipa ni nitõtọ:
13 Ọwọkọwọ́ kò gbọdọ kàn a, bikoṣepe ki a sọ ọ li okuta, tabi ki a gún u pa nitõtọ; iba ṣe ẹranko iba ṣe enia, ki yio là a: nigbati ipè ba dún, ki nwọn ki o gùn oke wá.
14 Mose si sọkalẹ lati ori oke na wá sọdọ awọn enia, o si yà awọn enia si mimọ́, nwọn si fọ̀ aṣọ wọn.
15 O si wi fun awọn enia pe, Ẹ mura dè ijọ́ kẹta: ki ẹ máṣe sunmọ aya nyin.