13 Nigbati o si jade lọ ni ijọ́ keji, kiyesi i, ọkunrin meji ara Heberu mbá ara wọn jà: o si wi fun ẹniti o firan si ẹnikeji rẹ̀ pe, Ẽṣe ti iwọ fi nlù ẹgbẹ rẹ?
14 On si wipe, Tali o fi ọ jẹ́ olori ati onidajọ lori wa? iwọ fẹ́ pa mi bi o ti pa ara Egipti? Mose si bẹ̀ru, o si wipe, Lõtọ ọ̀ran yi di mimọ̀.
15 Nigbati Farao si gbọ́ ọ̀ran yi, o nwá ọ̀na lati pa Mose. Ṣugbọn Mose sá kuro niwaju Farao, o si ngbé ilẹ Midiani: o si joko li ẹba kanga kan.
16 Njẹ alufa Midiani li ọmọbinrin meje, nwọn si wá, nwọn pọn omi, nwọn si kún ọkọ̀ imumi lati fi omi fun agbo-ẹran baba wọn.
17 Awọn oluṣọ-agutan si wá, nwọn si lé wọn kuro: nigbana ni Mose dide duro, o ràn wọn lọwọ, o si fi omi fun agbo-ẹran wọn.
18 Nigbati nwọn si padà dé lati ọdọ Reueli baba wọn, o ni Ẽtiri ti ẹnyin fi tète dé bẹ̃ loni?
19 Nwọn si wipe, Ara Egipti kan li o gbà wa lọwọ awọn oluṣọ-agutan, o si pọn omi to fun wa pẹlu, o si fi fun agbo-ẹran.