15 Ijọ́ mẹfa ni ki a ṣe iṣẹ; ṣugbọn ni ọjọ́ keje ni ọjọ́ isimi, mimọ́ ni si OLUWA: ẹnikẹni ti o ba ṣe iṣẹkiṣẹ li ọjọ́ isimi, on li a o si pa nitõtọ.
16 Nitorina li awọn ọmọ Israeli yio ṣe ma pa ọjọ́ isimi mọ́, lati ma kiyesi ọjọ́ isimi lati irandiran wọn, fun majẹmu titilai.
17 Àmi ni iṣe lãrin emi ati lãrin awọn ọmọ Israeli titilai: nitori ni ijọ́ mẹfa li OLUWA dá ọrun on aiye, ni ijọ́ keje o si simi, o si ṣe ìtura.
18 O si fi walã ẹrí meji, walã okuta, ti a fi ika Ọlọrun kọ, fun Mose, nigbati o pari ọ̀rọ bibá a sọ tán lori oke Sinai.