16 Wọnyi si li orukọ awọn ọmọ Lefi ni iran wọn; Gerṣoni, ati Kohati, ati Merari: ọdún aiye Lefi si jẹ́ mẹtadilogoje.
17 Awọn ọmọ Gerṣoni; Libni, ati Ṣimei, ni idile wọn.
18 Ati awọn ọmọ Kohati; Amramu ati Ishari, ati Hebroni, ati Ussieli ọdún aiye Kohati si jẹ́ ãdoje o le mẹta.
19 Ati awọn ọmọ Merari; Mahali, ati Muṣi. Wọnyi ni idile Lefi ni iran wọn.
20 Amramu si fẹ́ Jokebedi arabinrin baba rẹ̀ li aya, on li o si bi Aaroni ati Mose fun u: ọdún aiye Amramu si jẹ́ mẹtadilogoje.
21 Ati awọn ọmọ Ishari; Kora, ati Nefegi, ati Sikri.
22 Ati awọn ọmọ Ussieli; Miṣaeli, ati Elsafani, ati Sitri.