8 Emi o si mú nyin lọ sinu ilẹ na, ti mo ti bura lati fi fun Abrahamu, fun Isaaki, ati fun Jakobu; emi o si fi i fun nyin ni iní: Emi li OLUWA.
9 Mose si sọ bẹ̃ fun awọn ọmọ Israeli: ṣugbọn nwọn kò gbà ti Mose gbọ́ fun ibinujẹ ọkàn, ati fun ìsin lile.
10 OLUWA si sọ fun Mose pe,
11 Wọle, sọ fun Farao ọba Egipti pe, ki o jẹ ki awọn ọmọ Israeli ki o lọ kuro ni ilẹ rẹ̀.
12 Mose si sọ niwaju OLUWA wipe, Kiyesi i, awọn ọmọ Israeli kò gbọ́ ti emi, Farao yio ha ti ṣe gbọ́ ti emi, emi ẹniti iṣe alaikọlà ète?
13 OLUWA si bá Mose ati Aaroni sọ̀rọ, o si fi aṣẹ fun wọn si awọn ọmọ Israeli, ati si Farao, ọba Egipti, lati mú awọn ọmọ Israeli jade ni ilẹ Egipti.
14 Wọnyi li olori ile baba wọn: awọn ọmọ Reubeni akọ́bi Israeli; Hanoku, ati Pallu, Hesroni, ati Karmi: wọnyi ni idile Reubeni.