12 Nitoriti olukuluku nwọn fi ọpá rẹ̀ lelẹ, nwọn si di ejò: ṣugbọn ọpá Aaroni gbe ọpá wọn mì.
13 Aiya Farao si le, kò si fetisi ti wọn; bi OLUWA ti wi.
14 OLUWA si wi fun Mose pe, Aiya Farao di lile, o kọ̀ lati jẹ ki awọn enia na ki o lọ.
15 Tọ̀ Farao lọ li owurọ̀; kiyesi i, o njade lọ si odò; ki iwọ ki o si duro lati pade rẹ̀ leti odò; ati ọpá nì ti o di ejò ni ki iwọ ki o mú li ọwọ́ rẹ.
16 Iwọ o si wi fun u pe, OLUWA, Ọlọrun awọn Heberu, li o rán mi si ọ wipe, Jẹ ki awọn enia mi ki o lọ, ki nwọn ki o le sìn mi ni ijù: si kiyesi i, titi di isisiyi iwọ kò gbọ́.
17 Bayi li OLUWA wi, Ninu eyi ni iwọ o fi mọ̀ pe emi li OLUWA: kiyesi i, emi o fi ọpá ti o wà li ọwọ́ mi lù omi ti o wà li odò, nwọn o si di ẹ̀jẹ.
18 Ẹja ti o wà ninu odò na yio si kú, odò na yio si ma rùn; awọn ara Egipti yio si korira ati ma mu ninu omi odò na.