14 Nitori ìgba yi li emi o rán gbogbo iyọnu mi si àiya rẹ, ati sara awọn iranṣẹ rẹ, ati sara awọn enia rẹ; ki iwọ ki o le mọ̀ pe kò si ẹlomiran bi emi ni gbogbo aiye.
15 Nitori nisisiyi, emi iba nà ọwọ́ mi, ki emi ki o le fi ajakalẹ-àrun lù ọ, ati awọn enia rẹ; a ba si ti ke ọ kuro lori ilẹ.
16 Ṣugbọn nitori eyi pãpa li emi ṣe mu ọ duro, lati fi agbara mi hàn lara rẹ; ati ki a le ròhin orukọ mi ká gbogbo aiye.
17 Titi di isisiyi iwọ ngbé ara rẹ ga si awọn enia mi pe, iwọ ki yio jẹ ki nwọn ki o lọ?
18 Kiyesi i, li ọla li akokò yi, li emi o mu ọ̀pọ yinyin rọ̀ si ilẹ, irú eyiti kò ti si ni Egipti lati ipilẹṣẹ rẹ̀ titi o fi di isisiyi.
19 Njẹ nisisiyi ranṣẹ, ki o si kó ẹran rẹ bọ̀, ati ohun gbogbo ti o ni ninu oko; nitori olukuluku enia ati ẹran ti a ba ri li oko, ti a kò si múbọ̀ wá ile, yinyin yio bọ lù wọn, nwọn o si kú.
20 Ẹniti o bẹ̀ru ọ̀rọ OLUWA ninu awọn iranṣẹ Farao, mu ki awọn iranṣẹ rẹ̀ ati awọn ẹran-ọ̀sin rẹ̀ sá padà wá ile: