4 Laisi emi nwọn o tẹ̀ ba labẹ awọn ara-tubu, nwọn o si ṣubu labẹ awọn ti a pa. Ni gbogbo eyi ibinu rẹ̀ kò yi kuro, ṣugbọn ọwọ́ rẹ̀ nà jade sibẹ.
5 Egbe ni fun Assuri, ọgọ ibinu mi, ati ọ̀pa ọwọ́ wọn ni irúnu mi.
6 Emi o ran a si orilẹ-ède agabàgebe, ati fun awọn enia ibinu mi li emi o paṣẹ kan, lati ko ikogun, ati lati mu ohun ọdẹ, ati lati tẹ̀ wọn mọlẹ bi ẹrẹ̀ ni igboro.
7 Ṣugbọn on kò rò bẹ̃, bẹ̃ni ọkàn rẹ̀ kò rò bẹ̃; ṣugbọn o wà li ọkàn rẹ̀ lati parun ati lati ke orilẹ-ède kuro, ki iṣe diẹ.
8 Nitori o wipe, Ọba kọ awọn ọmọ-alade mi ha jẹ patapata?
9 Kalno kò ha dabi Karkemiṣi? Hamati kò ha dabi Arpadi? Samaria kò ha dabi Damasku?
10 Gẹgẹ bi ọwọ́ mi ti nà de ijọba ere ri, ere eyi ti o jù ti Jerusalemu ati ti Samaria lọ.