13 Nitorina emi o mu ọrun mì titi, ilẹ aiye yio si ṣipò rẹ̀ pada, ninu ibinu Oluwa awọn ọmọ-ogun, ati li ọjọ ibinu gbigbona rẹ̀.
14 Yio si dabi abo agbọ̀nrin ti a nlepa, ati bi agutan ti ẹnikan kò gbajọ: olukuluku wọn o yipada si enia rẹ̀, olukuluku yio si sa si ilẹ rẹ̀.
15 Ẹnikẹni ti a ri li a o gun li agunyọ; ẹnikẹni ti o si dà ara rẹ̀ pọ̀ mọ́ wọn yio ti ipa idà ṣubu.
16 Ọmọ wọn pẹlu li a o fọ́ tũtu loju ara wọn; a o si kó wọn ni ile, a o si fi agbara bà obinrin wọn jẹ́;
17 Kiyesi i, emi o gbe awọn ara Media dide si wọn, ti ki yio ka fadakà si; bi o si ṣe ti wura, nwọn ki yio ni inu didùn si i.
18 Ọrun wọn pẹlu yio fọ́ awọn ọdọmọkunrin tũtũ; nwọn ki yio ṣãnu fun ọmọ-inu: oju wọn kì yio dá ọmọde si.
19 Ati Babiloni, ogo ijọba gbogbo, ẹwà ogo Kaldea, yio dabi igbati Ọlọrun bi Sodomu on Gomorra ṣubu.