1 NITORI Oluwa yio ṣãnu fun Jakobu, yio si tun yan Israeli, yio si mu wọn gbe ilẹ wọn; alejò yio si dapọ̀ mọ wọn, nwọn o si faramọ ile Jakobu.
2 Awọn enia yio si mu wọn, nwọn o si mu wọn wá si ipò wọn: ile Israeli yio si ni wọn ni ilẹ Oluwa, fun iranṣẹkunrin ati iranṣẹbinrin: awọn ti o ti kó wọn ni igbekun ni nwọn o kó ni igbekun; nwọn o si ṣe akoso aninilara wọn.
3 Yio si ṣe li ọjọ ti Oluwa yio fun ọ ni isimi kuro ninu ibanujẹ rẹ, ati kuro ninu ijaiya rẹ, ati kuro ninu oko-ẹru lile nibiti a ti mu ọ sìn,
4 Ni iwọ o si fi ọba Babiloni ṣẹ̀fẹ yi, ti iwọ o si wipe, Aninilara nì ha ti ṣe dakẹ! alọnilọwọgbà wura dakẹ!
5 Oluwa ti ṣẹ ọpá oluṣe-buburu, ati ọpá-alade awọn alakoso.
6 Ẹniti o fi ibinu lù awọn enia lai dawọ duro, ẹniti o fi ibinu ṣe akoso awọn orilẹ-ède, li a nṣe inunibini si, lai dẹkun.
7 Gbogbo aiye simi, nwọn si gbe jẹ: nwọn bú jade ninu orin kikọ.