15 Ṣugbọn a o mu ọ sọkalẹ si ipò okú, si iha ihò.
16 Awọn ti o ri ọ yio tẹjumọ ọ, nwọn o si ronu rẹ pe, Eyi li ọkunrin na ti o mu aiye wárìrì, ti o mu ilẹ ọba mìtiti;
17 Ti o sọ aiye dàbi agìnju, ti o si pa ilu rẹ̀ run; ti kò dá awọn ondè rẹ̀ silẹ lati lọ ile?
18 Gbogbo ọba awọn orilẹ-ède, ani gbogbo wọn, dubulẹ ninu ogo, olukuluku ninu ile rẹ̀.
19 Ṣugbọn iwọ li a gbe sọnù kuro nibi iboji rẹ bi ẹka irira, bi aṣọ awọn ti a pa, awọn ti a fi idà gun li agunyọ, ti nsọkalẹ lọ si ihò okuta; bi okú ti a tẹ̀ mọlẹ.
20 A kì o sin ọ pọ̀ pẹlu wọn, nitoriti iwọ ti pa ilẹ rẹ run, o si ti pa awọn enia rẹ: iru awọn oluṣe buburu li a kì o darukọ lailai.
21 Mura ibi pipa fun awọn ọmọ rẹ̀, nitori aiṣedẽde awọn baba wọn; ki nwọn ki o má ba dide, ki nwọn ni ilẹ na, ki nwọn má si fi ilu-nla kun oju aiye.