20 A kì o sin ọ pọ̀ pẹlu wọn, nitoriti iwọ ti pa ilẹ rẹ run, o si ti pa awọn enia rẹ: iru awọn oluṣe buburu li a kì o darukọ lailai.
21 Mura ibi pipa fun awọn ọmọ rẹ̀, nitori aiṣedẽde awọn baba wọn; ki nwọn ki o má ba dide, ki nwọn ni ilẹ na, ki nwọn má si fi ilu-nla kun oju aiye.
22 Nitori emi o dide si wọn, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; emi o si ke orukọ ati iyokù kuro ni Babiloni, ati ọmọ, ati ọmọ de ọmọ, ni Oluwa wi.
23 Emi o si ṣe e ni ilẹ-ini fun õrẹ̀, ati àbata omi; emi o si fi ọwọ̀ iparun gbá a, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.
24 Oluwa awọn ọmọ-ogun ti bura, wipe, Lõtọ gẹgẹ bi mo ti gberò, bẹ̃ni yio ri, ati gẹgẹ bi mo ti pinnu, bẹ̃ni yio si duro:
25 Pe, emi o fọ́ awọn ara Assiria ni ilẹ mi, ati lori oke mi li emi o tẹ̀ ẹ mọlẹ labẹ ẹsẹ: nigbana li ajàga rẹ̀ yio kuro lara wọn, ati ẹrù rẹ̀ kuro li ejiká wọn.
26 Eyi ni ipinnu ti a pinnu lori gbogbo aiye: eyi si ni ọwọ́ ti a nà jade lori gbogbo orilẹ-ède.