18 Lõtọ ni, Oluwa, awọn ọba Assiria ti sọ gbogbo orilẹ-ède di ahoro, ati ilẹ wọn,
19 Nwọn si ti sọ awọn òriṣa wọn sinu iná: nitori ọlọrun ki nwọn iṣe, ṣugbọn iṣẹ ọwọ́ enia ni, igi ati òkuta: nitorina ni nwọn ṣe pa wọn run.
20 Njẹ nisisiyi, Oluwa Ọlọrun wa, gbà wa lọwọ rẹ̀, ki gbogbo ijọba aiye le mọ̀ pe iwọ ni Oluwa, ani iwọ nikanṣoṣo.
21 Nigbana ni Isaiah ọmọ Amosi ranṣẹ si Hesekiah, wipe, Bayi ni Oluwa Ọlọrun Israeli wi, niwọ̀n bi iwọ ti gbadura si mi niti Sennakeribu ọba Assiria:
22 Eyi ni ọ̀rọ ti Oluwa ti sọ niti rẹ̀: Wundia, ọmọbinrin Sioni, ti kẹ́gàn rẹ, o si ti fi ọ rẹrin ẹlẹyà; ọmọbinrin Jerusalemu ti mì ori rẹ̀ si ọ.
23 Tani iwọ kẹgàn ti o si sọ̀rọ buburu si? tani iwọ si gbe oju rẹ ga si, ti o si gbe oju rẹ soke gangan? si Ẹni-Mimọ́ Israeli ni.
24 Nipasẹ awọn iranṣẹ rẹ li o ti kẹgàn Oluwa, ti o si ti wipe, Ni ọ̀pọlọpọ kẹkẹ́ mi, emi ti goke wá si oke awọn oke giga, si ẹba Lebanoni; emi o si ke igi kedari rẹ̀ giga lulẹ, ati ãyò igi firi rẹ̀, emi o si wá si ẹnu agbègbe rẹ̀, ati si igbó Karmeli rẹ̀.