14 Tali o mba a gbìmọ, tali o si kọ́ ọ lẹkọ́, ti o si kọ́ ọ ni ọ̀na idajọ, ti o si kọ́ ọ ni ìmọ, ti o si fi ọ̀na oye hàn a?
15 Kiyesi i, awọn orilẹ-ède dabi iró kan ninu omi ladugbo, a si kà wọn bi ekúru kiun ninu ìwọn: kiyesi i, o nmu awọn erekùṣu bi ohun diẹ kiun.
16 Lebanoni kò si tó fi joná, bẹ̃ni awọn ẹranko ibẹ kò to lati fi rubọ sisun.
17 Gbogbo orilẹ-ède li o dabi ofo niwaju rẹ̀; a si kà wọn si fun u bi ohun ti o rẹ̀hin jù ofo ati asan lọ.
18 Tali ẹnyin o ha fi Ọlọrun we? tabi awòran kini ẹnyin o fi ṣe akàwe rẹ̀?
19 Oniṣọ̀na ngbẹ́ ère, alagbẹdẹ wura si nfi wura bò o, o si ndà ẹ̀wọn fadakà.
20 Ẹniti o talakà tobẹ̃ ti kò fi ni ohun ọrẹ, yàn igi ti kì yio rà; o nwá ọlọgbọn oniṣọ̀na fun ara rẹ̀ lati gbẹ́ ère gbigbẹ́ ti a ki yio ṣi nipò.