16 Lebanoni kò si tó fi joná, bẹ̃ni awọn ẹranko ibẹ kò to lati fi rubọ sisun.
17 Gbogbo orilẹ-ède li o dabi ofo niwaju rẹ̀; a si kà wọn si fun u bi ohun ti o rẹ̀hin jù ofo ati asan lọ.
18 Tali ẹnyin o ha fi Ọlọrun we? tabi awòran kini ẹnyin o fi ṣe akàwe rẹ̀?
19 Oniṣọ̀na ngbẹ́ ère, alagbẹdẹ wura si nfi wura bò o, o si ndà ẹ̀wọn fadakà.
20 Ẹniti o talakà tobẹ̃ ti kò fi ni ohun ọrẹ, yàn igi ti kì yio rà; o nwá ọlọgbọn oniṣọ̀na fun ara rẹ̀ lati gbẹ́ ère gbigbẹ́ ti a ki yio ṣi nipò.
21 Ẹnyin kò ti mọ̀? ẹnyin kò ti gbọ́? a kò ti sọ fun nyin li atètekọṣe? kò iti yé nyin lati ipilẹṣẹ aiye wá?
22 On ni ẹniti o joko lori òbíri aiye, gbogbo awọn ti ngbe ibẹ si dabi ẹlẹngà; ẹniti o ta ọrun bi ohun tita, ti o si nà wọn bi àgọ lati gbe.