1 DAKẸ niwaju mi, Ẹnyin erekùṣu; si jẹ ki awọn enia tún agbara wọn ṣe: jẹ ki wọn sunmọ tosí; nigbana ni ki wọn sọ̀rọ: jẹ ki a jumọ sunmọ tosí fun idajọ.
2 Tali o gbe olododo dide lati ìla-õrun wa, ti o pè e si ẹsẹ rẹ̀, ti o fi awọn orilẹ-ède fun u niwaju rẹ̀, ti o si fi ṣe akoso awọn ọba? o fi wọn fun idà rẹ̀ bi ekuru, ati bi akekù iyàngbo fun ọrun rẹ̀.
3 O lepa wọn, o si kọja li alafia; nipa ọ̀na ti kò ti fi ẹsẹ rẹ̀ tẹ̀ ri.
4 Tali o ti dá a ti o si ti ṣe e, ti o npè awọn iran lati ipilẹṣẹ̀ wá? Emi Oluwa ni; ẹni-ikini, ati pẹlu ẹni-ikẹhìn; Emi na ni.