2 Tali o gbe olododo dide lati ìla-õrun wa, ti o pè e si ẹsẹ rẹ̀, ti o fi awọn orilẹ-ède fun u niwaju rẹ̀, ti o si fi ṣe akoso awọn ọba? o fi wọn fun idà rẹ̀ bi ekuru, ati bi akekù iyàngbo fun ọrun rẹ̀.
3 O lepa wọn, o si kọja li alafia; nipa ọ̀na ti kò ti fi ẹsẹ rẹ̀ tẹ̀ ri.
4 Tali o ti dá a ti o si ti ṣe e, ti o npè awọn iran lati ipilẹṣẹ̀ wá? Emi Oluwa ni; ẹni-ikini, ati pẹlu ẹni-ikẹhìn; Emi na ni.
5 Awọn erekùṣu ri i, nwọn si bẹ̀ru; aiya nfò awọn opin aiye; nwọn sunmọ tosí, nwọn si wá.
6 Olukulùku ràn aladugbo rẹ̀ lọwọ; o si wi fun arakunrin rẹ̀ pe, Ẹ mu ara le.
7 Bẹ̃ni gbẹnàgbẹnà ngbà alagbẹdẹ wura niyànju, ati ẹniti nfi ọmọ-owú dán a, ngbà ẹniti nlù ògún niyànju; wipe, o ṣetan fun mimọlù: o si fi iṣo kàn a mọra ki o má le ṣi.
8 Ṣugbọn iwọ, Israeli, ni iranṣẹ mi, Jakobu ẹniti mo ti yàn, iru-ọmọ Abrahamu ọrẹ mi.