26 Tani o ti fi hàn lati ipilẹ̀ṣẹ, ki awa ki o le mọ̀? ati nigba iṣãju, ki a le wi pe, Olododo ni on? nitõtọ, kò si ẹnikan ti o fi hàn, nitõtọ, kò si ẹnikan ti o sọ ọ, nitõtọ, kò si ẹnikan ti o gbọ́ ọ̀rọ nyin.
27 Ẹni-ikini o wi fun Sioni pe, Wò o, on na nĩ: emi o fi ẹnikan ti o mú ihinrere wá fun Jerusalemu.
28 Nitori mo wò, kò si si ẹnikan; ani ninu wọn, kò si si olugbimọ̀ kan, nigbati mo bere lọwọ wọn, kò si ẹniti o le dahùn ọ̀rọ kan.
29 Kiyesi i, asan ni gbogbo wọn; asan ni iṣẹ wọn; ẹfũfu ati rudurudu ni ere didà wọn.