17 A o dá awọn ti o gbẹkẹle ere gbigbẹ́ padà, a o doju tì wọn gidigidi, awọn ti nwi fun ere didà pe, Ẹnyin ni ọlọrun wa.
18 Gbọ́, ẹnyin aditi; ki ẹ si wò, ẹnyin afọju ki ẹnyin ki o le ri i.
19 Tani afọju, bikoṣe iranṣẹ mi? tabi aditi, bi ikọ̀ mi ti mo rán? tani afọju bi ẹni pipé? ti o si fọju bi iranṣẹ Oluwa?
20 Ni riri nkan pupọ, ṣugbọn iwọ kò kiyesi i; ni ṣiṣi eti, ṣugbọn on ko gbọ́.
21 Inu Oluwa dùn gidigidi nitori ododo rẹ̀; yio gbe ofin ga, yio si sọ ọ di ọlọlá.
22 Ṣugbọn enia ti a jà lole ti a si ko li ẹrù ni eyi: gbogbo wọn li a dẹkùn mu ninu ihò, a fi wọn pamọ ninu tubu: a fi wọn fun ikogun, ẹnikan ko si gbà wọn; a fi wọn fun ikogun, ẹnikan ko si wipe, Mu u pada.
23 Tani ninu nyin ti o fi eti si eyi? ti o dẹti silẹ, ti yio si gbọ́ eyi ti mbọ̀ lẹhin?