12 Mo ti dá aiye, mo si ti da enia sori rẹ̀; Emi, ani ọwọ́ mi, li o ti nà awọn ọrun, gbogbo awọn ogun wọn ni mo si ti paṣẹ fun.
13 Mo ti gbe e dide ninu ododo, emi o si mu gbogbo ọ̀na rẹ̀ tọ́; on o kọ́ ilu mi, yio si dá awọn ondè mi silẹ: ki iṣe fun iye owo tabi ère, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.
14 Bayi li Oluwa wi, pe, Ere iṣẹ Egipti, ati ọjà Etiopia ati ti awọn ara Sabea, awọn enia ti o ṣigbọnlẹ yio kọja wá sọdọ rẹ, nwọn o si jẹ tirẹ: nwọn o tẹle ọ; ninu ẹwọ̀n ni nwọn o kọja wá, nwọn o foribalẹ fun ọ, nwọn o si bẹ̀ ọ, wipe, Nitotọ Ọlọrun wà ninu rẹ; kò si si ẹlomiran, kò si Ọlọrun miran.
15 Lõtọ iwọ li Ọlọrun ti o fi ara rẹ pamọ, Ọlọrun Israeli, Olugbala.
16 Oju yio tì wọn, gbogbo wọn o si dãmu pọ̀; gbogbo awọn ti nṣe ere yio si jumọ lọ si idãmu.
17 Ṣugbọn a o fi igbala ainipẹkun gba Israeli là ninu Oluwa: oju ki yio tì nyin, bẹ̃ni ẹ ki yio dãmu titi aiye ainipẹkun.
18 Nitori bayi li Oluwa wi, ẹniti o dá awọn ọrun; Ọlọrun tikararẹ̀ ti o mọ aiye, ti o si ṣe e; o ti fi idi rẹ̀ mulẹ, kò da a lasan, o mọ ọ ki a le gbe inu rẹ̀: Emi ni Oluwa; ko si ẹlomiran.