18 Kò si ẹnikan ninu gbogbo awọn ọmọ ọkunrin ti o bí lati tọ́ ọ; bẹ̃ni kò si ẹniti o fà a lọwọ, ninu gbogbo awọn ọmọ ọkunrin ti on tọ́ dàgba.
19 Ohun meji wọnyi li o débá ọ: tani o kãnu fun ọ? idahoro, on iparun, ati ìyan, on idà: nipa tani emi o tù ọ ninu?
20 Awọn ọmọ rẹ ọkunrin ti dáku, nwọn dubulẹ ni gbogbo ikorita, bi ẹfọ̀n ninu àwọn: nwọn kún fun ìrúnu Oluwa, ibawi Ọlọrun rẹ.
21 Nitorina gbọ́ eyi na, iwọ ẹniti a pọ́n loju, ti o si mu amuyo, ṣugbọn kì iṣe nipa ọti-waini:
22 Bayi ni Oluwa rẹ Jehofa wi, ati Ọlọrun rẹ ti ngbèja enia rẹ̀, Kiyesi i, emi ti gbà ago ìwárìri kuro lọwọ rẹ, gẹ̀dẹgẹ́dẹ̀ ago irúnu mi; iwọ kì yio si mu u mọ.
23 Ṣugbọn emi o fi i si ọwọ́ awọn ti o pọ́n ọ loju; ti nwọn ti wi fun ọkàn rẹ pe, Wólẹ, ki a ba le rekọja: iwọ si ti tẹ́ ara rẹ silẹ bi ilẹ, ati bi ita, fun awọn ti o rekọja.