1 TALI o ti gbà ihìn wa gbọ́? tali a si ti fi apá Oluwa hàn fun?
2 Nitori yio dàgba niwaju rẹ̀ bi ọ̀jẹlẹ ohun ọ̀gbin, ati bi gbòngbo lati inu ilẹ gbigbẹ: irísi rẹ̀ kò dara, bẹ̃ni kò li ẹwà, nigbati a ba si ri i, kò li ẹwà ti a ba fi fẹ ẹ.
3 A kẹgan rẹ̀ a si kọ̀ ọ lọdọ awọn enia, ẹni-ikãnu, ti o si mọ̀ ibanujẹ: o si dabi ẹnipe o mu ki a pa oju wa mọ kuro lara rẹ̀; a kẹgàn rẹ̀, awa kò si kà a si.
4 Lõtọ o ti ru ibinujẹ wa, o si gbe ikãnu wa lọ; ṣugbọn awa kà a si bi ẹniti a nà, ti a lù lati ọdọ Ọlọrun, ti a si pọ́n loju.
5 Ṣugbọn a ṣá a li ọgbẹ nitori irekọja wa, a pa a li ara nitori aiṣedede wa; ìna alafia wa wà lara rẹ̀, ati nipa ìna rẹ̀ li a fi mu wa lara da.
6 Gbogbo wa ti ṣina kirikiri bi agutan, olukuluku wa tẹ̀le ọ̀na ara rẹ̀; Oluwa si ti mu aiṣedede wa gbogbo pade lara rẹ̀.