1 KỌRIN, iwọ àgan, ti kò bi ri; bú si orin, si ké rara, iwọ ti kò rọbi ri; nitori awọn ọmọ ẹni-alahoro pọ̀ ju awọn ọmọ ẹniti a gbe ni iyawo: li Oluwa wi.
2 Sọ ibi agọ rẹ di gbigbõro, si jẹ ki wọn nà aṣọ tita ibugbe rẹ̀ jade: máṣe dási, sọ okùn rẹ di gigùn, ki o si mu ẽkàn rẹ le.
3 Nitori iwọ o ya si apa ọtún ati si apa osì, iru-ọmọ rẹ yio si jogun awọn keferi: nwọn o si mu ki awọn ilu ahoro wọnni di ibi gbigbe.
4 Má bẹ̀ru, nitori oju kì yio tì ọ: bẹ̃ni ki o máṣe dãmu; nitori a ki yio doju tì ọ; nitori iwọ o gbagbe itìju igbà ewe rẹ, iwọ kì yio sì ranti ẹ̀gan iwà-opo rẹ mọ.