12 Emi o fi rubi ṣe ṣonṣo-ile rẹ, emi o si fi okuta didán ṣe àsẹ rẹ; emi o si fi awọn okuta àṣayan ṣe agbègbe rẹ.
13 A o si kọ́ gbogbo awọn ọmọ rẹ lati ọdọ Oluwa wá; alafia awọn ọmọ rẹ yio si pọ̀.
14 Ninu ododo li a o fi idi rẹ mulẹ: iwọ o jina si inira; nitori iwọ kì yio bẹ̀ru: ati si ifoiya, nitori kì yio sunmọ ọ.
15 Kiye si i, ni kikojọ nwọn o kó ara wọn jọ, ṣugbọn ki iṣe nipasẹ mi; ẹnikẹni ti o ba ditẹ si ọ yio ṣubu nitori rẹ.
16 Kiye si i, emi li ẹniti o ti dá alagbẹ̀dẹ ti nfẹ́ iná ẹyín, ti o si mu ohun-elò jade fun iṣẹ rẹ̀; emi li o si ti dá apanirun lati panirun.
17 Kò si ohun-ijà ti a ṣe si ọ ti yio lè ṣe nkan; ati gbogbo ahọn ti o dide si ọ ni idajọ ni iwọ o da li ẹbi. Eyi ni ogún awọn iranṣẹ Oluwa, lati ọdọ mi ni ododo wọn ti wá, li Oluwa wi.