1 BAYI li Oluwa wi, Ẹ pa idajọ mọ, ẹ si ṣe ododo: nitori igbala mi fẹrẹ idé, ati ododo mi lati fi hàn.
2 Alabukun ni fun ọkunrin na ti o ṣe eyi, ati fun ọmọ enia ti o dì i mu: ti o pa ọjọ isimi mọ laisọ ọ di aimọ́; ti o si pa ọwọ́ rẹ̀ mọ kuro ni ṣiṣe ibi.
3 Ti kò si jẹ ki ọmọ alejò ti o ti dà ara rẹ̀ pọ̀ mọ́ Oluwa sọ, wipe; Oluwa ti yà mi kuro ninu awọn enia rẹ̀ patapata: bẹ̃ni kò jẹ ki ìwẹ̀fà wipe, Wò o, igi gbigbẹ ni mi.
4 Nitori bayi li Oluwa wi fun awọn ìwẹfa ti nwọn pa ọjọ isimi mi mọ, ti nwọn si yàn eyi ti o wù mi, ti nwọn si di majẹmu mi mu;
5 Pe, emi o fi ipò kan fun wọn ni ile mi, ati ninu odi mi, ati orukọ ti o dara jù ti awọn ọmọkunrin ati ọmọ-obinrin lọ: emi o fi orukọ ainipẹkun fun wọn, ti a kì yio ke kuro.
6 Ati awọn ọmọ alejò ti nwọn dà ara pọ̀ mọ Oluwa, lati sìn i, ati lati fẹ orukọ Oluwa, lati jẹ iranṣẹ rẹ̀, olukuluku ẹniti o pa ọjọ isimi mọ laisọ ọ di aimọ́, ti o si di majẹmu mi mu;