18 A kì yio gbọ́ ìwa-ipá mọ ni ilẹ rẹ, idahoro tabi iparun li agbègbe rẹ; ṣugbọn iwọ o pe odi rẹ ni Igbala, ati ẹnu-bodè rẹ ni Iyin.
19 Õrùn kì yio jẹ imọlẹ rẹ mọ li ọsan, bẹ̃ni oṣupa kì yio fi imọlẹ rẹ̀ ràn fun ọ; ṣugbọn Oluwa yio ṣe imọlẹ ainipẹkun rẹ, ati Ọlọrun rẹ ogo rẹ.
20 Õrùn rẹ ki yio wọ̀ mọ; bẹ̃ni oṣupa rẹ kì yio wọ̃kùn: nitori Oluwa yio jẹ imọlẹ ainipẹkun fun ọ, ọjọ ãwẹ̀ rẹ wọnni yio si de opin.
21 Ati awọn enia rẹ, gbogbo wọn o jẹ olododo: nwọn o jogun ilẹ na titi lailai, ẹka gbigbin mi, iṣẹ ọwọ́ mi, ki a ba le yìn mi logo.
22 Ẹni-kekere kan ni yio di ẹgbẹrun, ati kekere kan yio di alagbara orilẹ-ède: emi Oluwa yio ṣe e kankan li akokò rẹ̀.