10 Ṣugbọn nwọn ṣọ̀tẹ, nwọn si bi Ẹmi mimọ́ rẹ̀ ninu; nitorina li o ṣe pada di ọta wọn, on tikalarẹ̀ si ba wọn ja.
11 Nigbana ni o ranti ọjọ atijọ, Mose, awọn enia rẹ̀, wipe, Nibo li ẹniti o mu wọn ti inu okun jade gbe wà, ti on ti olùṣọ agutan ọwọ́-ẹran rẹ̀? nibo li ẹniti o fi Ẹmi mimọ́ rẹ̀ sinu rẹ̀ gbe wà?
12 Ti o fi ọwọ́ ọtun Mose dà wọn, pẹlu apá rẹ̀ ti o logo, ti o npin omi meji niwaju wọn, lati ṣe orukọ aiyeraiye fun ara rẹ̀?
13 Ti o mu wọn là ibú ja, bi ẹṣin li aginjù, ki nwọn ki o má ba kọsẹ?
14 Gẹgẹ bi ẹran ti isọ̀kalẹ lọ si afonifoji, bẹ̃ni Ẹmi Oluwa mu u simi: bẹ̃ni iwọ tọ́ awọn enia rẹ, lati ṣe orukọ ti o li ogo fun ara rẹ.
15 Wò ilẹ lati ọrun wá, ki o si kiyesi lati ibugbe ìwa mimọ́ rẹ ati ogo rẹ wá: nibo ni itara rẹ ati agbara rẹ, ọ̀pọlọpọ iyanu rẹ, ati ãnu rẹ sọdọ mi gbe wà? a ha da wọn duro bi?
16 Laiṣiyemeji iwọ ni baba wa, bi Abrahamu tilẹ ṣe alaimọ̀ wa, ti Israeli kò si jẹwọ wa: iwọ Oluwa, ni baba wa, Olurapada wa; lati aiyeraiye ni orukọ rẹ.