Isa 66:14-20 YCE

14 Nigbati ẹnyin ba ri eyi, ọkàn nyin yio yọ̀, egungun nyin yio si tutu yọ̀yọ bi ewebẹ̀; a o si mọ̀ ọwọ́ Oluwa lara awọn iranṣẹ rẹ̀, ati ibinu rẹ̀ si awọn ọta rẹ̀.

15 Nitori kiyesi i, Oluwa mbọ wá ti on ti iná, ati awọn kẹkẹ́ rẹ̀ bi ãjà, lati fi irunu sẹsan ibinu rẹ̀, ati ibawi rẹ̀ nipa ọwọ́ iná.

16 Nitori Oluwa yio fi iná ati idà rẹ̀ ṣe idajọ gbogbo ẹran-ara; awọn okú Oluwa yio si pọ̀.

17 Awọn ti o yà ara wọn si mimọ́, ti nwọn si sọ ara wọn di mimọ́ ninu agbala wọnni, ti ọkan tẹle ekeji li ãrin, nwọn njẹ ẹran ẹlẹdẹ, ati ohun irira, ati eku, awọn li a o parun pọ̀; li Oluwa wi.

18 Nitori emi mọ̀ iṣẹ ati ìro wọn: igba na yio dé lati ṣà gbogbo awọn orilẹ-ède ati ahọn jọ, nwọn o si wá, nwọn o si ri ogo mi.

19 Emi o si fi àmi kan si ãrin wọn, emi o si rán awọn ti o salà ninu wọn si awọn orilẹ-ède, si Tarṣiṣi, Puli, ati Ludi, awọn ti nfà ọrun, si Tubali, on Jafani, si awọn erekuṣu ti o jina rére, ti nwọn kò ti igbọ́ okiki mi, ti nwọn kò si ti iri ogo mi; nwọn o si rohin ogo mi lãrin awọn Keferi.

20 Nwọn o si mu gbogbo awọn arakunrin nyin lati orilẹ-ède gbogbo wá, ẹbọ kan si Oluwa lori ẹṣin, ati ninu kẹkẹ́, ati ninu páfa, ati lori ibaka, ati lori rakunmi, si Jerusalemu oke-nla mimọ́ mi; li Oluwa wi, gẹgẹ bi awọn ọmọ Israeli ti imu ọrẹ wá ninu ohun-elò mimọ́ sinu ile Oluwa.