18 Nitori emi mọ̀ iṣẹ ati ìro wọn: igba na yio dé lati ṣà gbogbo awọn orilẹ-ède ati ahọn jọ, nwọn o si wá, nwọn o si ri ogo mi.
19 Emi o si fi àmi kan si ãrin wọn, emi o si rán awọn ti o salà ninu wọn si awọn orilẹ-ède, si Tarṣiṣi, Puli, ati Ludi, awọn ti nfà ọrun, si Tubali, on Jafani, si awọn erekuṣu ti o jina rére, ti nwọn kò ti igbọ́ okiki mi, ti nwọn kò si ti iri ogo mi; nwọn o si rohin ogo mi lãrin awọn Keferi.
20 Nwọn o si mu gbogbo awọn arakunrin nyin lati orilẹ-ède gbogbo wá, ẹbọ kan si Oluwa lori ẹṣin, ati ninu kẹkẹ́, ati ninu páfa, ati lori ibaka, ati lori rakunmi, si Jerusalemu oke-nla mimọ́ mi; li Oluwa wi, gẹgẹ bi awọn ọmọ Israeli ti imu ọrẹ wá ninu ohun-elò mimọ́ sinu ile Oluwa.
21 Ninu wọn pẹlu li emi o si mu ṣe alufa ati Lefi; li Oluwa wi.
22 Nitori gẹgẹ bi awọn ọrun titun, ati aiye titun, ti emi o ṣe, yio ma duro niwaju mi, bẹ̃ni iru-ọmọ rẹ ati orukọ rẹ yio duro, li Oluwa wi.
23 Yio si ṣe, gbogbo ẹran-ara yio si wá tẹriba niwaju mi, lati oṣù titun de oṣù titun, ati lati ọjọ isimi de ọjọ isimi, li Oluwa wi.
24 Nwọn o si jade lọ, nwọn o si wò okú awọn ti o ti ṣọtẹ si mi: nitori kokoro wọn kì yio kú, bẹ̃ni iná wọn kì yio si kú; nwọn o si jẹ ohun irira si gbogbo ẹran-ara.