1 IWỌ máṣe ilara si awọn enia buburu, bẹ̃ni ki o má si ṣe fẹ lati ba wọn gbe.
2 Nitoriti aiya wọn ngbiro iparun, ète wọn si nsọ̀rọ ìwa-ika.
3 Ọgbọ́n li a fi ikọ ile; oye li a si fi ifi idi rẹ̀ kalẹ.
4 Nipa ìmọ ni iyará fi ikún fun oniruru ọrọ̀ iyebiye ati didùn.
5 Ọlọgbọ́n enia li agbara: nitõtọ enia ìmọ a sọ agbara rẹ̀ di pupọ.
6 Nitori nipa ìgbimọ ọgbọ́n ni iwọ o fi ṣigun rẹ: ati ninu ọ̀pọlọpọ ìgbimọ ni iṣẹgun.
7 Ọgbọ́n ga jù aṣiwère lọ: on kì yio yà ẹnu rẹ̀ ni ẹnu-bode.