22 Nitoripe wàhala wọn yio dide lojiji, ati iparun awọn mejeji, tali o mọ̀ ọ!
23 Wọnyi pẹlu ni ọ̀rọ awọn ọlọgbọ́n. Kò dara lati ṣe ojuṣãju ni idajọ.
24 Ẹniti o ba wi fun enia buburu pe, olododo ni iwọ; on ni awọn enia yio bú, awọn orilẹ-ède yio si korira rẹ̀.
25 Ṣugbọn awọn ti o ba a wi ni yio ni inu-didùn, ibukún rere yio si bọ̀ sori wọn.
26 Yio dabi ẹniti o ṣe ifẹnukonu: ẹniti o ba ṣe idahùn rere.
27 Mura iṣẹ rẹ silẹ lode, ki o si fi itara tulẹ li oko rẹ; nikẹhin eyi, ki o si kọ́ ile rẹ.
28 Máṣe ẹlẹri si ẹnikeji rẹ lainidi: ki iwọ ki o má si ṣe fi ète rẹ ṣẹ̀tan.