5 Ọlọgbọ́n enia li agbara: nitõtọ enia ìmọ a sọ agbara rẹ̀ di pupọ.
6 Nitori nipa ìgbimọ ọgbọ́n ni iwọ o fi ṣigun rẹ: ati ninu ọ̀pọlọpọ ìgbimọ ni iṣẹgun.
7 Ọgbọ́n ga jù aṣiwère lọ: on kì yio yà ẹnu rẹ̀ ni ẹnu-bode.
8 Ẹniti nhùmọ ati ṣe ibi li a o pè li enia ìwa-ika.
9 Ironu wère li ẹ̀ṣẹ; irira ninu enia si li ẹlẹgàn.
10 Bi iwọ ba rẹwẹsi li ọjọ ipọnju, agbara rẹ ko to nkan.
11 Bi iwọ ba fà sẹhin ati gbà awọn ti a wọ́ lọ sinu ikú, ati awọn ti a yàn fun pipa.